JM Free Ebooks - шаблон joomla Форекс
Smaller Default Larger

Ijinle Ohun Enu Ifa Apa Keji

ijinle_ohun_enu_ifa_apa_keji_cover
Ìjìnlẹ̀ Ohùn Ẹnu Ifá Apá Kejì ni èkejì nínú ọ̀wọ́ ìwé tí ó tú pẹrẹpẹ́rẹ̀ lórí ẹsẹ Ifá. Ó jẹ́ ìtèsíwájú fún Apá Kìn-ín-ní. A ṣe àkoṣílẹ̀ àwọn ẹsẹ méjọméjọ nínú àwọn ẹsẹ Ifá tí ó wà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ...Read more
  • Description

Ìjìnlẹ̀ Ohùn Ẹnu Ifá Apá Kejì ni èkejì nínú ọ̀wọ́ ìwé tí ó tú pẹrẹpẹ́rẹ̀ lórí ẹsẹ Ifá. Ó jẹ́ ìtèsíwájú fún Apá Kìn-ín-ní. A ṣe àkoṣílẹ̀ àwọn ẹsẹ méjọméjọ nínú àwọn ẹsẹ Ifá tí ó wà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ojú odù mẹ́rẹ̀ẹ̀rìndínlógún, bẹ̀rẹ̀ láti orí Èjì ogbè títí dé orí Òfún méjì.

Ìwé yìí tún gbìyánjú sàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ta kókó nínú àwọn ẹsẹ Ifá wònyí tí ó ṣe é ṣe kí ó jẹ́ ìdààmú fún olùkọ́, akẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn ònkàwé wa gbogbo.

Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ìwé yìí, ìsòrò ẹsẹ Ifá gẹ́gẹ́ bi ọ̀kan nínú àwọn ewì alohùn Yorùbá ti di ìrọ̀rùn.

Òjò ni ìwé yìí, bọ́ ṣe dára fún ọmọdé bẹ́ẹ̀ ló wúlò fún àgbà.

Àfín tí kò nílò à-ún-júwe lójà ni Ọ̀jọ̀gbọ́n ’Wándé Abímbọ́lá nínú onímọ̀ ní gbogbo àgbáyé. Ó ti gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé àti iṣé ìwádìí papàá lórí Ifá jáde.